This is a condensed, translated version of the 2020 Census website in Yoruba.

Èyí jẹ́ àdéhùn, ẹdà itumọ ti 2020census.gov. Tẹ ibiyi lati pada si ààyè ní kíkún ti èdè Gẹẹsi ati Sipanisi.

Skip Header

Ìkànìyàn 2020 | Ilé-iṣẹ́ Ìkànìyàn Amẹ́ríkà

Component ID: #ti2071972765

Shape your future.

START HERE.

#9B2743
ÀJỌPÍN:

Bí a tile F'ìfè sí Ìkànìyàn 2020 Náà

Itọni Rẹ si Ìkàniyàn 2020 Náà

Ka àwọn ìtọ́nisọ́nà lórí bí o ṣe le parí ìbéèrè ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò.

Download PDF
pdf   Yorùbá   [1.5 MB]

Ẹnikan latinu ibùgbé kọọkan gbọdọ́parí ìkànìyàn lori ayélujára, nípasẹ̀ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tabi kíkọ ìwé ayélujára ráńṣé. Ka gbogbo àwọn tí ó ń gbé ní àdírẹ́ẹ̀sì náà– ati awọn ọmọ-àsẹ̀sẹ̀bí, ọmọ-kéékèèké, ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí tí wọ́n ń gbé tí wọ́n sì ń sùn níbẹ̀ni ọpọ igbà.

Bí ẹnìkan tí kò ní ibùgbé títí láí bá wà níbí ní Ọjọ́ kínní, oṣù kẹrin ọdún 2020, ka ènìyàn náà.

Ṣe ètò Ìkànìyàn náà lórí ayélujára

Ìwé ìbéèrè ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lórí ayélujára ti wà l'àrọ́wọ́tó. Bí o bá nílò ìrànlọ́wọ́, lo àwọn ìtọ́nisọ́nà tó wà ní ìsàlẹ̀.

Ǹjẹ́ O Nílò Ìrànlọ́wọ́?

Fún ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú ìkànìyàn 2020 náà, tàbí f'èsì pẹ̀lú nípasẹ̀ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, pe 844-330-2020. À ń dáhùn àwọn ìpè ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, Spáníìṣì, Ṣainisi, Fíẹ́tínàmù, Kòrìà, Rọ́ṣíà, Lárúbáwá, Tágálọ̀gì, Pọ́líṣì, Faransé, Hàítì, Kíréólè, Pọ́túgì, àti Jápánísì.

#008556

Kínni Ìkànìyàn náà?

Ìkànìyàn 2020 ka gbogbo àgbàlagbà, ọmọ-ọwọ́, àti ọmọdé ti ń gbé ní Ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Kíkà yìí ma ń wáyé ní ọdún mẹ́wàá mẹ́wàá nípasẹ̀ Ilé-iṣẹ́ Ìkànìyàn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ilé-iṣẹ́ ìjọba.

An overhead look at a suburban community.
#007E8F

Ìdí Tí ó fi ṣe Pàtàkì

Ìkànìyàn náà ńpèsè détà tí ó ṣe pàtàkì tí ó lè ṣètò oríṣiríṣi ìpele ayé rẹ. Àwọn aṣòfin, àwọn olókoòwò, àwọn olùkọ́ ati àwọn míràn ń lo détà yí l'ójojúmọ́ láti pèsè àwọn iṣẹ́, àwọn èlò-ọjà, àti àtìlẹyìn nínú àwùjọ rẹ.

Component ID: #ti1214996291

Ní ọdọọdún, bílíọ̀nùn dọ́là ní owó ìjọba àpapọ̀ ma ń jẹ́ níná fún àwọn ilé ìwòsàn, àwọn ẹ̀ka ilé-ìṣẹ́ panápaná, àwọn ilé ìwé, àwọn ọ̀nà, àti ohun èlò míràn tó dá lórí détà ìkànìyàn.

Component ID: #ti1262992577

Àwọn èsi ìkànìyàn ló ń ṣe àfihàn ìpinnu lórí iye ìjókòó tí ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní nínu Ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin , òhun ni wọ́n sì ń lò láti fa ààlà fún ìdìbò àwọn agbègbè.

Component ID: #ti1262184412

Ìkànìyàn náà sì wúlò fún ìwé Òfin Ilẹ̀ Amẹ́ríkà: Átíkù Kínní, Ìpín Kejì, pa dandan fún Ilẹ̀ Amẹ́ríkà láti ṣètò kíka àwọn ènìyàn ní ẹ̀kan láàrin ọdún mẹ́wa. Ìkà àkọ́kọ́ wáyé ní 1970.

#205493

Àṣírí àti Ààbò

Àwọn ìdáhùn rẹ ni a fi ṣe àwọn ìtúpalẹ̀ détà nìkan.

Woman smiling and using her phone while holding her baby.

Òfin wà fún Ilẹ̀-Iṣẹ́ Ìkànìyàn náà láti dáàbò bo àwọn ìdáhùn rẹ kí ó sì ìpamọ́ fún etígbọ̀ kẹta. Kódà, gbogbo òṣìṣẹ́ ń búra láti dáàbò bo ìwífún-ni rẹ títí láyé.

Lábẹ́ Àkọlé kẹtàlá tí kódù Ilé Amẹ́ríkà, Ilé-Iṣẹ́ Ìkànìyàn náà kò le yọ̀da ìwífún-ni ìdánimọ̀ nípa rẹ, ilé rẹ, tàbí iṣẹ́ rẹ, kódà fún àwọn ẹ̀ka agbófinró. Òfin náà ri dájú wípé détà àṣírí rẹ wà ní ìdáàbò bò àti wípé kò sì ẹ̀ka Ilé-iṣẹ́ ìjọba tàbí ilé-ẹjọ́ kan tí ó le lo àwọn ìdáhùn rẹ láti takò ọ́.

#008556

Àwọn Olùkànìyàn ní Àdúgbò Rẹ

Ju ọdún tó ń bọ̀ lọ, o lè ṣ'àkíyèsí àwọn olùkànìyàn ní àdúgbò rẹ.

Close-up of a census taker's hand holding a mobile phone.
Component ID: #ti1399515519

Èyí jẹ́ apákan déédéé ètò Ìkànìyàn 2020. Ó seése kí o rí àwọn òṣìṣẹ́ ìkànìyàn ní àdúgbò rẹ fún àwọn ìdí kan tàbí òmíràn:

  • Wọ́n ń àyẹ̀wò àwọn àdírẹ́ẹ̀sì fún ìmúrasílẹ̀ ìkànìyàn náà.
  • Wọ́nń bẹ àwọn ibùgbé wó fún èto ìkànìyàn tàbí ìwádíì Ilé-iṣẹ́ Ìkànìyàn míràn.
  • Wọ́n ń fi àwọn àlàyé nípa ìkànìyàn s'ílẹ̀.
  • Wọ́n ń ṣ'àyẹ̀wò lórí iṣẹ́ tó jẹ mọ́ èto ìkànìyàn.

Nínú oṣù karùn-ún 2020, àwọn olùkànìyàn yóò bẹ̀rẹ̀ sí bẹ àwọn ilé wò tí kò tíì f'èsì sí ìkànìyàn 2020 náà láti ri wípé gbogbo ènìyàn ni wọ́n kà.

#9B2743

Bí O Ṣele Ṣ'èrànlọ́wọ́

Láti gba ìkànìyàn to péye ni 2020 nílò àtìlẹyìn oníkálukú, àti wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà ló wà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan, àwọn iṣẹ́, ẹgbẹ́ ìlú, àti àwọn míràn láti ṣe ìrànlọ́wọ́.

Component ID: #ti836858766
Component ID: #ti931891026

Tan Ọ̀rọ̀ náà ká

O lè ràn wá lọ́wọ́ nípa títan ìròyìn àti ìwífún-ni Ilé-Iṣẹ́ Ìkànìyàn pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, ẹbí, àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ lórí Facebook, Twitter, àti Instagram.

Component ID: #ti1723517893
Component ID: #ti1125182455
Component ID: #ti462505476

Ṣe Alábàṣepọ̀ Pẹ̀lú Wa

Ọgọgọ̀rún àwọn Ilé-Iṣẹ́, àwọn ẹgbẹ́-aláàánú, àwọn aláṣẹ àti àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ń tan ọ̀rọ̀ kalẹ nípa èto Ìkànìyàn 2020 àti ìdí tí ó fi ṣe pàtàkì láti kópa.

Component ID: #ti403709881
Component ID: #ti1622390989
Component ID: #ti1243933241

Pín Àwọn Ohun Èlò

Ilé-Iṣẹ́ Ìkànìyàn náà ń pèsè àwọn orísun ètò-ẹ̀kọ́ nípa èto Ìkànìyàn 2020 láti ṣe ìrànlọ́wọ́ láti kópa àwọn agbègbè.